
Nuhu Gidado to je gomina ipinle Bauchi ti kowe fise sile.
Ogbeni Gidado so fun gomina ipinle Bauchi, Muhammed Abubakar lojo kẹ́rìndínlógún, osu kárùn ún lati fi ipinnu re han pe oun yoo fise sile.
Ninu leta ti ogbeni Gidado ko, lo ti salaye pe ,oun kowe fise sile lati tele ipinnu oun pe eekansoso ni oun yoo se ijoba gege bi igbakeji gomina fun ipinle naa.
O so pe “lotito,lo ye ki n wa nipo di igba ti ijoba wa yoo fi pari, sugbon eri okan mi ati irewesi ti mo n ri lenu ise ko lee je ki n tesiwaju lati je olotito si iwo egbon mi ati asiwaju mi”.
Siwaju si i, igbakeji gomina tun ran gomina leti nipa ipade ti won se ni ojo kọ́kàndínlógún, osu kẹ́rin pe oun, n ronu lati fise sile.
Ogbeni Gidado wa dupe lowo gomina ati awon omo ipinle naa fun anfaani lati sin won gege bi igbakeji gomina fun ipinle naa.
No comments:
Post a Comment