
Aare Muhammadu Buhari ti foruko awon marun un ti yoo je igbimo ti yoo maa sakoso ile ifowopamo ti ijoba apapo(CBN) ranse si ile –igbimo asofin agba lati fonte lu awon oruko naa.
Ninu iwe ti aare ko si adari ile igbimo asofin, ni eyi ti won ka nile-igbimo asofin agba lojoRu.Awon eniyan marun un naa wa, lati ekun maraaarun ti orile ede yii.
Oruko ti won fi ranse naa ni : Ummu Jalingo (Ila-oorun), Justina Nnabuko (Ila oorun- Gusu ), Mike Obadan (Ila Gusu), Abdu Abubakar (Ila -Ariwa) and Adeola Adetunji (Iwo oorun ).
Leyin ti adari igbimo asofin Bukola Saraki ka oruko awon eniyan marun un naa, o wa foruko won ranse si igbimo to n ri si ile-ifowopamo ati ajo ma –da-mi-dofo fun ayewo finni-finni. O wa tun pase fun adari igbimo naa Asofin Rafiu Ibrahim, lati jabo fun ile igbimo asofin leyin ose meji.
Asofin Ahmad Lawan, adari egbe to poju nile igbimo asofin lo koko pe akiyesi ile si ayewo oruko awon eniyan ti aare fi ranse, o wa fi ofin abala 6(1) (d) ati 10(1) ati (2) ti ile ifowopamo ti ijoba apapo,odun 2007 gbe e lese”.
Asofin Godswill Akpabio lo sikeji aba Ahmad Lawan .Ti a o ba gbagbe pe ni osu kerin odun 2017 ni aare Buhari ti koko foruko awon eniyan marun un naa ranse sile igbimo asofin lati gbaa wole , sugbon ti won faake kori nitori awuye-wuye to waye laarin ile igbimo asofin ati ojogbon Yemi Osinbajo lasiko ti igbakeji aarei n dele fun aare , pe ile-igbimo asofin ko ni agbara lati fi onte lu Ibrahim Magu gege bi oludari ile-ise ajo to n ri si sise owo ilu kumo-kumo (EFCC)
Ni osu keta, odun yii ni ile-igbimo asofin fowo-wonu, ti won si fonte lu awon igbakeji adari ile-ifowopamo ti ijoba meji ati awon meta fun igbimo ti yoo maa sakoso eto inawo labe ile-ifowopamo naa.
Lose to koja ni alaga igbimo asofin to n ri si eto eyawo ti abele ati oke-okun asofin Shehu Sani ro awon akegbe re nile igbimo asofin lati gbese kuro lori sise ayewo awon igbimo ile ifowopamo naa.
O wa ran awon akegbe re leti ofin abala kẹ́tàlélógójì ti odun 2015 ti atunse wa lori re, pe, ti ile- igbimo asofin agba ko ba gba oruko awon eniyan naa wole, yoo dekun ise ti o ye ki ile- ifowopamo ti ijoba apapo na maa se ku.
No comments:
Post a Comment