Aare Robert Mugabe ti orile-ede Zimbabwe ti setan lati yan igbakeji obinrin akoko iru re leyin ipade pata ki egbe oselu ti wa lori alefa lorile-ede ohun losu to n bo, aya aare ohun so lojo-abameta (Saturday) pe ko si ohun to buru ti oko oun ba yan oun si ipo naa.
Omo odun metaleladorun aare Mugabe ti wa lori alefa latigba ti orile-de ohun ti gb ominira ni odun 1980, ni ey ti o ko lati yan eni ti yoo gba ipo lowo re, O salaye pe, egbe-oselu ZANU-PF yoo yan eni ti yoo gba ipo naa bi oun ba setan lati feyin ti.
Aya aare naa Grace Mugabe so nibi iwode egbe-oselu ZANU-PF ti o waye nilu Bulawayo pe, egbe ohun yoo mu aunto ba ilana iwe ofin re ninu osu ti a wa yii, ni eyi ti won yoo fowo si atunse naa ninu ipade egbe-oselu naa ti yoo waye ninu osu kejila, lati ri daju pe, okan lara igbakeji aare Mugabe yoo je obinrin.
Fifaye gba aare Mugabe lati yan obinrin gege bi igbakeji yoo je ona fun igbakeji aare ohun Emmerson Mnangagwa, eni ti won ri gege bi eni ti yoo gba ipo lowo aare Mugabe, phelekezela Mphoko ni enikeji igbakeji aare Mugabe, amo ko ni imo eto-oselu to peye.
Lojo-abameta (Saturday) Grace gbogun ti Mnangagwa, ni eyi ti o so pe oun ni o sokunfa ipinya awon omo-egde oselu won, bakan naa ni o fesun kana won alatileyin igbakeji wipe, wonpariwo le oun lori nigba ti oun n baa won eniyan soro.
Grace so ninu oro re lori ero amohunmaworan orile-ede na pe, “Saaju ipade pata ki naa, a gbodo mu atunse ba iwe ofin ninu osu ti a wa yii, nigba ti a ba kuro lori alefa, a ti wa ninu akosile pe okan lara igbakeji aare gbodo je obinrin”.
Aya aare naa so pe, “Bi mo ba wole gege bi igbakeji aare? Kilo wa ninu? Se mi si ninu egbe oselu naa, ti awon eniyan ba mo pe, mo sise takuntakun ati pe bi won ba fe sise pelu mi, kilo wa ninu re?”
No comments:
Post a Comment