Naijiria gba ife eye FIBA Afrika 3×3 - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog


Tuesday, 7 November 2017

Naijiria gba ife eye FIBA Afrika 3×3


D-Tigers
Iko okunrin agbaboolu afowogba (basket ball) ti orile-ede Naijiria ti fagba han orile-ede Ivory Coast, ninu asekagba idije (FIBA) Afrika 3×3, eyi ti o waye nilu Lome, lorile-ede Togo,  pelu ami ayo mokanlelogun si mesan (21-9 ), lojo aiku(Sunday).
Bakan naa, ni awon iko obinrin orile-ede Naijiria gbe igbakeji ninu irufe ere idaraya ohun leyin ti iko obinrin orile-ede Mali fagba han iko ohun ninu asekagba idije naa pelu ami ayo mejila si mokanla (12-11).
Iko okunrin orile-ede Naijiria kun fun: Azuoma Dike, Godwin David, Lucky Subel ati Yahaya Abdul, leyi ti iko obinrin si kun fun Nkechi Akashili, Deborah Nwakamma, Josette Anaswem ati Nkem Akaraiwe.
Ni afikun, ninu idije ohun, orile-ede Naijiria yege ninu ifigagbaga otooto marun-un lati gba ife eye idije naa, ti orile-ede Ivory Coast  ati Madagascar si tele ra won.
Awon Esi ifigagbaga iko okunrin orile-ede Naijiria ki won o to jawe olubori laarin awon akegbe won lati gba ife eye ohun:
Naijiria ati Madagascar ami ayo mokanlelogun si merindinlogun (21-16)
Naijiria ati Niger ami ayo mokanlelogun si mewa (21-10)
Naijiria ati Benin ami ayo mokanlelogun si mejila (21-12)
Naijiria fagba han orile-ede Egypt pelu ami ayo mokanlelogun si merinla (21-14), ninu ipele keji si asekagba idije naa.
Naijiria ati Ivory Coast ami ayo mokanlelogun si mesan (21-9 )
Ninu idije tawon obinrin, orile-ede Mali gba ife eye ohun, ti orile-ede Naijiria si se ipo keji.

No comments:

Post a Comment