Ajo INEC kede ojo atundi idibo gomina ipinle Osun - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog


Tuesday, 25 September 2018

Ajo INEC kede ojo atundi idibo gomina ipinle Osun



Ajo to n mojuto eto idibo lorile-ede Naijiria, (Independent National Electoral Commission) INEC ti kede ojoBo(Thursday), ojo ketadinlogbon osu kesan, odun ti a wayii gege bi ojo atundi ibo gomina ipinle Osun.
Asoju ajo INEC ninu idibo naa, ojogbon Joseph Fowape, salaye lojo Aiku(Sunday) pe, awon ibo lati ibudo idibo kookan nipinle naa bi, ijoba ibile Ife North, Orolu ati Ife South ko si ni ibamu pelu ofin ati ilana ajo INEC, eleyi ti o sokunfa idi ti ajo INEC se fagile egbejidilogun-din-ọgọrun ibo ti o wa lati awon ibudo idibo ohun.
Ojogbon Fuwape, leni ti o tun je oga agba ile-iwe giga fafiti onimo-ero, Federal University of Technology, niluu Akure, so pe ibo ti o wa laarin egbe oselu mejeeji ti o n gbe igba oroke lowo kere si apapo ibo ti won fagile.
O wa fi oro re mule pe, gege bi ofin ati ilana ajo INEC, nikorita bayii, won gbodo tun idibo naa di ni, eleyi ti eto idibo atundi naa yoo si waye lojoBo(Thursday).
Bee si ni, gbogbo egbe oselu mejidinlaadọta ti o foruko sile fun idibo naa ni yoo tun kopa ninu atundi idibo ohun.

No comments:

Post a Comment