NAF se atunto si ipo awon oga agba méjílélógójì - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog


Friday 6 July 2018

NAF se atunto si ipo awon oga agba méjílélógójì



Ile-ise omo-ogun oju ofurufu Naijiria, NAF  ti se atunto si ipo awon oga agba méjílélógójì  jake-jado orile-ede Naijiria.
Atunto ohun ni o kunfun: awon igbakeji adari oko ofurufu mẹ́rìndínlógún(16 Air Vice Marshals),  Air Commodores mẹ́rìndínlógún, ogagun mẹ́sán án (Group Captains),  Wing Commander méje ati Squadron Leader mẹ́rin .
Gege bi atejade kan lati odo oga agba fun eto iroyin ati igbode-gba nile ise omo-ogun naa, Olatokunbo Adesanya, O ni: lara awon atuntuo ohun simo lori tun ni, awon oga agba oloye merin ti o wa lolu ile-ise omo-ogun naa ati oga agba adari oko ofurufu kan.
O fikun oro re pe,“pataki atunto ipo ohun ni lati ri daju pe, onikaluku n se ojuse ise re bi o se to ati bi o se ye.”
Adesanya tesiwaju pe, awon oga agba ti won sese yan ni: AVM Charles Otegbade, leni ti o je oga agba to n mojuto eka sise agbakale eto nile ise NAF, ni bayii, oun ni oga agba eka eto ibanisoro ati iforotonileti (CCIS).
Bakan naa, AVM Kingsley Lar, leni ti o je oga agba fun eka tee-ko to, ni bayii, O di oga agba eka isakoso.
Awon miiran tun ni: adari agba teleri fun ile-eko ija nipinle Makurdi, AVM John Baba, bee si ni, AVM Napoleon Bali, AVM Charles Oghomwen, AVM AS Liman,  Commodore BB Okunola, Commodore James Gwani.

No comments:

Post a Comment