Egbẹ̀rún lona mẹ́ta ebi je anfaani eto ilera ofe - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog


Friday 6 July 2018

Egbẹ̀rún lona mẹ́ta ebi je anfaani eto ilera ofe



Ajo to n mojuto ipese eto ilera nipinle Cross River(Primary Healthcare Development Agency), ti pese eto ilera ofe fun Egbẹ̀rún lona mẹ́ta ebi ti o n gbe lagbegbe eka ila oorun ipinle Cross River.
Oludaru agba ajo ohun, Dokita Betta Edu ni o tuko awon osise re lo silu Ukelle ti o wa nijoba ibile Yala Local Government nipinle Cross River, loile-ede Nigeria.
Adele gomina ipinle ohun, ojogbon Ivara Esu ati Dokita Edu, ni won jo pawo po lati pin ounje, awon ohun elo ipese ounje, aso, ohun elo igbonse abbl fun awon alabarapa ati awon alaisan ni agbegbe naa.
Oludari agba ohun, Dokita Edu wa lo anfaani naa lati ro ijoba apapo ati ijoba ipinle lati dojuko awon isoro pe-pee-pe ti o n koju awon agbegbe abele lolokan-o-jokan lati pese awon ohun amayederun fun awon agbegbe ohun nipase sise amulo awon eka ke-kee-ke ile-ise to n pese eto ilera ofe fun awon ara ilu (Primary Healthcare Centres, PHCs)
E faaye gba igbe-aye alafia
Ewe, ni kete ti eto ipese iwosan ofe ohun pari, adele gomina ohun, ojogbon Esu ati igbakeji gomina ipinle Ebonyi, ogbeni Eric Igwe pelu apapo awon agbaagba agbegbe ohun ti o fi mo awon oloselu lo jo jiroro bi igbe-aye alafia yoo se joba lagbegbe naa.

No comments:

Post a Comment