Aare Buhari fowosi ipese ise nipase eto ogbin - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog


Friday, 16 March 2018

Aare Buhari fowosi ipese ise nipase eto ogbin



Aare Muhammadu Buhari ti fi idunnu re han lori igberu ti o n ba eto ogbin, igbese kan gboogi lati pese ise fun awon odo langba lorile-ede Naijiria.
Nigba ti o n gbalejo minisita fun oro ile okere lorile-ede Tunisia, Boukekri Rmilli nile-ise Aare lojo-Isegun nilu Abuja, Aare Buhari so pe, isakoso oun yoo se alekun atileyin fun eto ogbin, ti o je ona kan gboogi lati pese ise.
Aare  Buhari so pe, “A n sa gbogbo akitiyan wa lati pese ise fun awon odo wa, a n igbese to nipon ni eka eto ogbin, latari sege-sege oja epo-robi ati airise se awon eniyan lorile-ede Naijiria, a setan lati fi igbagbo wa sori eto ogbin, inu mi dun pe awon odo langba wa n sise agbe bayii dipo ki won maa duro de ise alakowe, won n laagun ninu oorun lowolowo, eyi ti won yoo kere re laipe, tori pe eto ogbin ni ona abayo lowo ti a wa yii”.
O fi kun oro re pe, oun mo akitiyan ti isakoso ijoba orile-ede Tunisia ti gbe lori eto ogbin, irinajo afe, ati eto-ilera, laipe ojo, a o se agbekale iko kan ti yoo se abewo si orile-ede ohun lati mo awon eka ti awon orile-ede mejeeji ohun yoo ti sise papo.
Ninu oro re, o fi idunnu re han nipa agbende ipade apero  iko laarin orile-ede mejeeji, eyi ti ogoro awon asoju ni olokan-o-jokan eka ati awon onisowo jankan-jankan ti kopa.
Rmilli, eni ti o dari iko awon onisowo lati orile-ede Tunisia so fun Aare naa pe, orile-ede oun n saniyan lori amugberu eto oro-aje pelu orile-ede Naijira.
O fi idunnu re han lori bi awon oludokowo se jade lopo yanturu lati kopa nibi apapo ipade apero awon olokowo orile-ede Naijiria ati orile-ede Tunisia to waye nilu Abuja lojo-Aje.
Minisita oun jise pataki fun Aare Buhari, ninu eyi ti Aare orile-ede Tunisia Beji Caid Essebsi, ti ki olori orile-ede Nigeria ku oriire fun aseyori ninu eto-abo, oro-aje ati ipa ti o n ko ni ile Afrika.

No comments:

Post a Comment