Adajo agba kan lorile-ede Zimbabwe ti so pe, esun ti won fi kan omo orile-ede America kan wipe, o gbiyanju ati fipa gbajoba aare Mugabe, ko ni eri kan gboogi ninu, ni eyi ti o so pe, ki won da obinrin naa sile.
Martha O’Donovan ti wa lewon lati ojo-abameta (Saturday), leyin ojo kan ti won fi owo sinku ofin mu, latari esun pe, o soro alufansa si aare Mugabe lori ero ayelujara, awon olopaa tun fesun to le kan, eyi ti o kere yoo fewon ogun odun gbara.
Arabinrin naa se awon esun wonyii, arabinrin O’Donovan n sise nile-ise Maganba Television, eni ti o sapejuwe ara re gege bi akoroyin lori oro oselu pata ki kan lorile-ede Zimbabwe no oun n se.
Nigba ti o n da obinrin naa sile, adajo agba ohun Clement Phiri so pe, “ko si otito kan soso ninu oro naa”.
Phiri so pe, “ eni afesun kan ohun ti so pe, ki won da oun sile, oun si ri ninu iwadii pe, yoo safaani fun eto idajo ti a ba le da eni afesun kan naa sile”.
Ile-ise ti o n ri oro idajo lori ero ayelujara (Twitter) so pe, arabinrin naa ko sori ero Twitter ninu osu kewaa odun yii pe, aare Mugabe je “aladaje ati alaileran eniyan”. Ni eyi ti o mu ki ijoba se idasile ile-ise ti yoo ma samoju to eto-abo ori ero ayelujara losu to koja.
Arabinrin O’Donovan ko si nile ejo, amo adajo Phiri so pe ki o san $1.000 sile-ejo naa, ki o si jowo iwe iranna re, bakan naa ki o maa fara han niwaju eka ti o n se iwadii nigba meji laarin ose, gege bi okan lara igbese ti o fun ni ominira.
Agbejoro re, Obey Shaya so pe, won yoo daarabinrin O’Donovan sile lojo-eti (Friday) leyin ti o ba pari gbogbo ofin ti won la kale fun tan.
No comments:
Post a Comment