Boko Haram mefa ju awa sile fawon eso NSCDC nipinle Borno - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog


Wednesday, 13 September 2017

Boko Haram mefa ju awa sile fawon eso NSCDC nipinle Borno

Awon eso ara ilu awa ara wa, NSCDC ni awon omo Boko Haram mefa ti fi ara won sile nipinle Borno. Ogbeni Bulus James to je agbenuso ajo NSCDC lo soro yii nilu Maiduguri labe eto alaafia tijoba apapo gbe kale.
O ni opolopo awon agbesunmomi ni won ti setan lati fiwa buruku won sile ki won si di omoluwabi lawujo. James menuba awon ise akanse ti won ti se lati satileyin fawon omo ogun ile lati polongo lodi siwa agbesunmomi ni Naijiria.
DreamHost
O ni: Ïpolongo yii wa fun idagbasoke alaafia ati nini oye eto aabo to yaranti ki gbogbo osise eleto aabo le jo sise papo. Lojo kesan an osu yii ni awon akosemose lori eto aabo gba iyonda lati ibudo ikoni ni Fafiti Maiduguri. A n ro awon osise eleto aabo ti aladani naa lati pese ifitonileti to ye si ona ati fopin si isoro eto aabo Naijiria”
James kilo fawon osise eleto aabo aladani ti ko tii foruko sile bi o ti ye pe ki won lo se ohun to ye lasiko bi bee ko, won yoo gba iwe ase won lowo won nipinle Borno.
Won seto iforijin labe ase ijoba apapo fawon to ba setan lati yipada lawujo ki o le tun fi wu awon onise ibi Boko Haram lati yipada sii.
Opolopo awon onise ibi Boko Haram to ti yipada ni won n dalekoo fun osu meta nibudo awon Ologun ni Gombe bayii.

No comments:

Post a Comment